Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 29, 2017
BÒLÍFÍÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Torí Bí Wọ́n Ṣe Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Bòlífíà Yọ Níbi Àpéjọ Àgbègbè Wọn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Torí Bí Wọ́n Ṣe Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Bòlífíà Yọ Níbi Àpéjọ Àgbègbè Wọn

ÌLÚ SANTA CRUZ, lórílẹ̀-èdè Bolivia—Láti October 27 sí 29, 2017, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún (17,000) èèyàn láti orílẹ̀-èdè ogún (20) tó wá sípàdé àgbègbè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Cochabamba, lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Ìpàdé náà wú àwọn aláṣẹ lórí débi pé iléeṣẹ́ méjì ní Bòlífíà ló fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ torí pé wọ́n tún ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà ṣe lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì ṣe ìpàtẹ kan tó jẹ́ káwọn èèyàn rí oríṣiríṣi àṣà ìbílẹ̀ táwọn ọmọ ilẹ̀ Bòlífíà ní.

Àtọ̀dún 2012 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe àpéjọ àgbègbè nínú ọgbà Fundación para la Feria Internacional de Cochabamba (ìyẹn FEICOBOL). Ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbá ilẹ̀ ọgbà náà kó tó di ọjọ́ tí àpéjọ máa bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ lọ́dún yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa wá, torí náà, kí wọ́n lè múra sílẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (4,900) ló yọ̀ǹda ara wọn láti tún ọgbà náà ṣe tinú tòde, ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló sì gbà wọ́n. Lára iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n kun ilé, wọ́n ṣe àwọn páìpù omi, wọ́n sì ṣètò àwọn ohun èlò tó máa jẹ́ kí wọ́n lè gbóhùn sáfẹ́fẹ́ kí wọ́n sì wo fídíò. Wọ́n tún ṣe àfikún iṣẹ́ ní ìta ọgbà náà, bíi ríro àyíká, títún àwọn bẹ́ǹṣì ìjókòó àti iná ẹ̀gbẹ́ títì ṣe.

Àmì ẹ̀yẹ tí iléeṣẹ́ FEICOBOL fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú yẹn ṣètò ibì kan tí wọ́n pàtẹ àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí. Wọ́n fi ìpàtẹ yìí dá àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (1,800) tí wọ́n wá síbi àpéjọ náà láti àwọn orílẹ̀-èdè míì lẹ́kọ̀ọ́ nipa àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Bòlífíà. Lára ohun tí wọ́n pàtẹ ni àwọn nǹkan tí wọ́n ń gbìn nílẹ̀ wọn àtàwọn àwòrán tí wọ́n kùn sára ògiri. Bákan náà, wọ́n ṣe ilé mẹ́ta síbi tí wọ́n pàtẹ sí yìí. Àwọn ilé yìí jẹ́ kí àwọn tó wá síbẹ̀ rí bí wọ́n ṣe máa ń kọ́lé ní Bòlífíà, àwọn Ẹlẹ́rìí ò sì gbé àwọn ilé náà nígbà tí wọ́n ń lọ, ṣe ni wọ́n fi sílẹ̀ fún iléeṣẹ́ FEICOBOL.

Àmì ẹ̀yẹ tí Àjọ Tó Ń Rí sí Àṣà Ìbílẹ̀ Cochabamba fún wọn.

Aldo Vacaflores, tó jẹ́ ààrẹ ìgbìmọ̀ tó ń darí iléeṣẹ́ FEICOBOL, fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ torí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Ó sọ pé, “Bí àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì yín ṣe fi gbogbo ọkàn ṣiṣẹ́ wú wa lórí gan-an.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìtara gidi lẹ fi ṣiṣẹ́ yìí, ẹ sì fi ara yín jìn, kódà, gbogbo ọkàn lẹ fi ṣe é kí gbogbo àwọn tó bá wá sí [àpéjọ] yìí lè gbádùn ẹ̀. Àá máa fi tiyín ṣe àpẹẹrẹ fáwọn míì.”

Ìpàtẹ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe wú Àjọ Tó Ń Rí sí Àṣà Ìbílẹ̀ Cochabamba lórí, ni ọ́fíìsì ìjọba ìpínlẹ̀ Cochabamba yìí bá fún wọn ní àmì ẹ̀yẹ. Sdenka Fuentes, tó jẹ́ ààrẹ àjọ náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n yàn láti ṣe àpéjọ àgbègbè wọn nílùú Cochabamba. Ó ní ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n pàtẹ jẹ́ káwọn èèyàn rí oríṣiríṣi àṣà ìbílẹ̀ táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Bòlífíà ní lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí jẹ́ káwọn èèyàn rí àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Bòlífíà.

Garth Goodman, tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bòlífíà sọ pé: “Àǹfààní ńlá ni àpéjọ àgbègbè yìí fún àpapọ̀ àwọn tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún (49,320), tó fi mọ́ àwọn tó wà nílùú mẹ́fà míì tá a tàtagbà àpéjọ náà sí, láti jọ jọ́sìn Ọlọ́run. Inú wa dùn pé àwọn aráàlú mọyì ohun tá a ṣe láti fi hàn pé a ka orílẹ̀-èdè Bòlífíà àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí.”

Àtọdún 1924 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2017, ohun pàtàkì méjì ni wọ́n gbé ṣe. Wọ́n mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì (tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé) jáde ní èdè Quechua àti Aymara.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Bòlífíà: Garth Goodman, +591-3-342-3442