AUGUST 15, 2019
POLAND
Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Warsaw, Poland
Déètì: August 9 sí11, 2019
Ibi Tó Ti Wáyé: Pápá Ìṣeré Municipal Stadium of Legia nílùú Warsaw àti Gbọ̀ngàn Ìwòran Torwar Hall, nílùú Warsaw, lórílẹ̀-èdè Poland
Èdè: Gẹ̀ẹ́sì, Polish
Àwọn Tó Wá: 32,069
Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 190
Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 6,892
Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Central Europe, Chile, Ecuador, Finland, Faransé, Jọ́jíà, Hungary, Japan, Kòríà, Moldova, Romania, Ukraine, Amẹ́ríkà
Ìrírí: Ọ̀gbẹ́ni KamilKaźmierkiewicz tó jẹ́ ọ̀gá àgbà òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń pè ní Four Points by Sheraton ní ìlú Warsaw Mokotów (ó jẹ́ ọ̀kan lára òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n fi àwọn àlejò wọ̀ sí), kọ̀wé pé: “Ó rọrùn láti bá a yín ṣiṣẹ́, ó wù mí kí n tún láwọn àlejò tó jẹ́ onínúure tí wọ́n sì lẹ́mìí tó dáa bíi tiyín. Mo kíye síi pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín gan an, ẹ sì wà níṣọ̀kan. . . . Bẹ́ ẹ ṣe ṣètò gbogbo nǹkan ní àpéjọ yìi wú mi lórí gan-an.”
Ọ̀gbẹ́ni Kamil Lubański tó ni ilé iṣẹ́ KL Team tó bá wa ṣètò ọkọ̀ tó kó àwọn èèyàn sọ pé: “Látọjọ́ tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ ni mo ti mọ̀ pé màá gbádùn àkókò tá a máa fi ṣiṣẹ́. Wọ́n wà létòletò, wọ́n sì mọ́ nǹkan ṣe. Wọ́n ti ṣètò tó nítumọ̀ fún àpéjọ ńlá yìí, wọ́n sì ti múra sílẹ̀ dáadáa. Ọ̀pọ̀ àwọn olókìkí èèyàn la ti bá ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ wa, títí kan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, a sì ti ṣètò ìkórajọ káàkiri orílẹ̀-èdè yìí àti láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Yúróòpù. Àmọ́, mi ò tíì ráwọn èèyàn tó múra sílẹ̀ tó sì ṣe nǹkan létòletò bíi tiyín rí. Kókó ibẹ̀ ni pé, gbogbo àwọn awakọ̀ wa àtàwọn òṣìṣẹ́ wa míì ló ń sọ ohun tó dáa nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ iwájú, ó wù wá ká tún jọ ṣiṣẹ́.”
Wọ́n ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ ní ibùdókọ̀ òfuurufú
Àwọn àlejò ń dé síbi tá a ti ṣe àpéjọ náà láàárọ̀ Friday
Àwòrán ọ̀kàn lára ibi tá a ti ṣe àwọn àpẹ́jọ náà, Pápá Ìṣeré Municipal Stadium of Legia, nílùú Warsaw
Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ Friday
Mẹ́ta lára àwọn tó ṣèrìbọmi lọ́jọ́ Saturday
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́
Àwọn àlejò ń fi aṣọ ìbílẹ̀ wọn ya fọ́tò lẹ́yìn pápá ìṣeré náà
Lọ́jọ́ Sunday, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wà lórí papa ìṣéré náà, wọ́n sì ń kọrin ìparí pẹ̀lú àwùjọ
Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan ń kọrin fáwọn àlejò níbi ìkórajọ kan nírọ̀lẹ́
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń jó ijó ìbílẹ̀ àwọn ará Poland níbi ìkórajọ kan nírọ̀lẹ́