Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 2, 2019
TAJIKISTAN

Àwọn Aláṣẹ Ìlú Tajik Ju Arákùnrin Shamil Khakimov, Ẹni Ọdún Méjìdínláàádọ́rin (68) Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje Àtààbọ̀ Lọ́nà Tí Kò Tọ́

Àwọn Aláṣẹ Ìlú Tajik Ju Arákùnrin Shamil Khakimov, Ẹni Ọdún Méjìdínláàádọ́rin (68) Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje Àtààbọ̀ Lọ́nà Tí Kò Tọ́

Ní September 10, 2019, ilé ẹjọ́ ìlú Khujand ní Tajikistan fi Arákùnrin Shamil Khakimov sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje àtààbọ̀ kìkì nítorí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn míì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2019 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fojú Arákùnrin Khakimov rí màbo. Ní February 26, 2019, àwọn aláṣẹ mú Shamil, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin (68), wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ń “mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì.” Ni ilé ẹjọ́ bá fi sí àtìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, oṣù mẹ́fà ló lò níbẹ̀. Yàtọ̀ sí wàhálà ti pé wọ́n sọ Arákùnrin Khakimov sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru ń bá a fínra, èyí tó ṣì ń gba ìtọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́.

Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ju ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n ní Tajikistan látọdun 2017. Nígbà yẹn wọ́n ju Danil Islamov tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún (18) sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà torí pé ó kọ̀ láti wọ aṣọ ológun. Tajikistan náà ti wà lára àwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún tó ti ju ó kéré tán, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rin tó kù ni Eritrea, Rọ́ṣíà, Singapore àti Turkmenistan.

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa báa lọ láti fún Arákùnrin Khakimov ní gbogbo ohun tó nílò láti fara da àdańwò yìí.​—Róòmù 15:5.